BREAKING NEWS

ÌDÍJE TIWALÁṢÀ ÌPÍNLẸ̀ OGÚN TI ỌDÚN UN 2020 FÚN ÌGBÉLÁRUGẸ ÀṢÀ ÀTI ÈDE YORÙBÁ LÁÀÁRÍN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ-Ẹ̀KỌ́ GIRAMA

Ìdíje Tiwaláṣà jẹ́ ìdíje ọlọ́dọọdún tí ó máa ń wáyé láàárín àwọn ilé ẹ̀kọ́ girama ni gbogbo ilẹ̀ Kóòótù-oò-jíire. (Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀yọ́, Ògùn, Èkìtì, Òǹdó àti Ọ̀ṣun).



A dá ètò ìdíje Tiwaláṣà silẹ láti máa fi ṣe ìgbélárugẹ àti láti fi máa fi rán wa lÉtí àṣà, ìṣe àti ẹwà èdè ohùn ẹnu Yorùbá pàápàá láàárín àwọn èwe àti màjèṣín àsìkò yìí kí àwọn náà lè máa kọ́ nípa ìwà ọmọlúwàbí tó sodo sínú Àṣà àti Ìṣe àwa Yorùbá àti ipa tó jọjú fún ìmúgbòòrò Àṣà àti Ède Yorùbá.


Wọ̀nyìí ni bí ètò ìdíje Tiwaláṣà fún ti ọdún un 2020 yóò ti ṣe lọ ní ìpínlẹ̀ Ògùn.




"ÌLÀNÀ ÌDÍJE TIWALÀSÀ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN 2020."

Ẹkùn: Rẹ́mọ: 
Ojó kerin osù kejì
Odún yí
Methodist comp college, Sagamu


Ẹkùn' ìjẹ̀bú:
Ọjọ́ karùn-ún ọdún yí
Adéolá Odùtótá college ìjẹ̀bú ode.

Ẹkùn Yewa:
Ojó kefà osù kejì odún yí. Yewa college ìlaró


Ẹkùn Ègbá:
Ojó keje osù kejì odú yí: Ilé èko gíga Lísàbi ìdí àbà, Abéòkúta


Àsekágbá:
Ojó kokànlá osù kejì odún yí
Ilé èkó Lísàbi ìdí àbà
Abéòkúta
Agogo méjo áàrò.


À fí àsìkò yí rọ gbogbo èyin olólùfé wá té wà ní ìpínlè Ògùn pé kẹ́ ẹ dara pọ̀ mọ́ wa.


Olùrànlọ́wọ́ ní ẹgbẹ́:
"ÌṢỌ̀KAN ỌMỌ ODÙDUWÀ FOUNDATION (ISOOF)"
 

Ilé iṣẹ ṢỌLÁTỌ́LÁ PRODUCTION ló ṣe agbátẹrù ìdíje náà nígbà tí OLÓYÈ YÈYÉ TỌ́LÁNÍ ỌLÁDOSÙ IFÁKỌ̀YÀ jẹ́ OLÙDÁSÍLẸ̀ Ìdíje Tiwaláṣà.


No comments

After Dropping your comment, Wait for few minutes, your comments will appear below!!!