BREAKING NEWS

Today's Leader's Forum Praise 2019: ÀṢÀ ÀTI ÌṢE YORÙBÁ : Ọ̀NÀ KAN GBOGI LÁTI DẸKÙN ÌWÀ IBAJẸ LÁWÙJỌ - ISOLA SAUBAN ALADE

ÀṢÀ ÀTI ÌṢE YORÙBÁ : Ọ̀NÀ KAN GBOGI LÁTI DẸKÙN ÌWÀ IBAJẸ LÁWÙJỌ

ISOLA SAUBAN ALADE

(ii) Àwùjọ
Bí a bá ń sọ nípa àwùjọ, eléyìí túmọ̀ sí ìlú, àdúgbò, ilé ìwé, ilé ìjọsìn àti àwọn tí ọmọ ń bá á rìn. Tí ọmọ bá ń gbé láàrin àwùjọ tí àwọn ìwà jàǹdùkú bí olè, panṣágà, àgbèrè, ìmọtípara, òfófó, irọ́ pípa, ìwà ipá àti bẹ́ẹ̀  bẹ́ẹ̀  lọ wà irú ọmọ bẹ́ẹ̀  kò lè ṣoríire àyàfi tí Ọlọ́run bá kó o yọ  torí pé ẹ̀dá kò lè dára tàbí wúlò ju àwùjọ rẹ̀  lọ. Àmọ́, ọmọ tó bá ń gbé ibi tí sùúrù, ìwà pẹ̀lẹ́, ìkóra-ẹni-níjánu, ìlòdì-sí-òfófó, ìlòdì-sí-àgbèrè, panṣ ágà àti bẹ́ẹ̀  bẹ́ẹ̀  lọ bá wà yóò di ọmọlúàbí tí orí inú rẹ̀  kò bá ta kò ó.


(iii) Ìjọba
Irúfẹ́ ìjọba tí ó wà lóde ló máa ń sọ bí ìwà ọmọlúàbí tàbí jàǹdùkú yóò ṣe gbilẹ̀  tó. Tí àwọn alákóso orílẹ̀-èdè, ìpínlẹ̀, ìjọba ìbílẹ̀ , àwọn ọba àti ìjòyè kò bá lọ́wọ́ sí ìwà jàǹdùkú bí olè, ìwà ipá, àgbèrè, panṣágà, àti bẹ́ẹ̀  bẹ́ẹ̀  lọ, ìwà ọmọlúàbí yóò gbilẹ̀  ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀  ìwà búburú yóò gbòde kan. Eléyìí lè jẹ yọ nínú irúfẹ́ofin tí à ń lò bí a ṣe ń lò ó láìṣègbè sí ìwà tí àwọn tó wà lórí oyè ń hù.


Ìjọba tó ń dáàbò bo àwọn abàlújẹ torí pé wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́òṣ èlú àti ìmùlẹ̀  kan náà kò lè káwọ́ ìwà búburú to tako ìwà ọmọlúàbí rárá. Ìjọba tó ń ṣà àbò lórí àwọn olè, onífàyàwọ́ , apànìyàn àti amúnisìn kò le è ran ìwà ọmọlúàbí lọ́ wọ́ rárá. Àwọn ọba àti ìlú náà gbọ́dọ̀ gba ìwà ọmọlúàbí láàyè.


(iv) Ilé-Iṣẹ́ Ìròyìn
A lè pín ilé-iṣẹ́ ìròyìn sí ọ̀nà mẹ́ta – Rédíò, Tẹlẹfísàn, àti ìwé ìròyìn. Àwọn wọ̀nyí gbọ́dọ̀ gbà láti mú ìwà ọmọlúàbí tẹ̀ síwájú láwùjọ.


(v) Àjọ òǹkọ̀wé
Àwọn òǹkọ̀wé náà máa ń lo ìwé wọn láti gbé ìwà ọmọlúàbí lárugẹ tàbí ti ìwà jàǹdùkú lẹ́yìn.


Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé inú ọkàn ni ọ̀rọ̀, ìṣesí, ìhùwàsí àti oríṣìí gbogbo n̄ǹkan mìíràn tí àwa ẹ̀dá ń ṣe ti ń sun jáde. Fún ìdí èyí, wọn kì í gba àwọn ọmọdé láyè láti ronú lọ́nà òdì, kí wọ́n máà ba tàpá sí òfin àti èèwọ̀ inú àwùjọ wọn. Kí èrò ọkàn àwọn ọmọ wọn lè bá ojú-àmúwayé wọn mu, wọn a ti máa kọ́ wọn ní gbogbo ẹ̀kọ́ tí ó jẹ mọ́ àṣà àti ìṣe pẹ̀lú ẹ̀sin ìbílẹ̀ wọn láti ìgbà èwe. Yàtọ̀ sí èyí, akitiyan ṣíṣe lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan jẹ́ èyí tí ó ní ipa lórí ètò-ìlera àwọn ẹ̀dá. Nítorí náà ni wọ́n fi máa ń ṣẹ̀dá àwọn ewì alohùn tó jẹ mọ́ ìdárayá ṣíṣe bí ijó jíjó, orin kíkọ, ìfò fífò àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ fún awọn ọmọ wọn. Èyí ni yóò sì lè jẹ́ kí wọ́n lè máa lo àwọn ẹ̀yà ara wọn tí ọkàn jẹ́ olúborí wọn nínú àwọn ìdárayá bẹ́ẹ̀.  


Moronkọ́lá (2002:152) tilẹ̀ sọ nípa ipa pàtàkì tí akitiyan ìdárayá ṣíṣe kó nínú ètò-ìlera àwọn ọmọdé pé:
On the premise of the Yorùbá people, they usually engaged their children on physical activities in order to promote their health. 


Health promotion is the process of enabling children at their tender age to increase control over problems and to improve their health. To reach a state of complete physical, mental and social wellbeing, an individual or group must be able to identify and to realize aspirations, to satisfy needs, and to change or cope with the environment. 


(Nínú àwùjọ àwọn Yorùbá, wọ́n máa ń sábà ṣe àgbékalẹ̀ àwọn akitiyan ajẹmọ́-ìlera fún wọn, kí wọ́n lè mú ìdàgbàsókè bá ètò-ìlera àwọn ọmọ náà. 


Akitiyan tí ó jẹ mọ́ àmúgbòòrò ètò-ìlera ni ìlànà tí wọ́n lò láti mú kí àwọn ọmọdé lè borí àwọn ìṣòro kan nígbà èwe wọn, àti láti jẹ́ kí ara wọn le sí i. Kí a tó lè gbà pé ènìyàn ní ìlera tó péye, ní ìrísí rẹ̀, nínú ìrònú rẹ̀, nínú ìṣesí àti ìhùsí rẹ̀ láwùjọ, ó di dandan kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lè ṣe àṣeyọrí àti àgbéjáde èròǹgbà wọn, kí wọ́n lè tẹ́ ara wọn tàbi àwùjọ lọ́rùn, kí wọ́n sì le máa hu àwọn ìwà tí ó bá ti àwùjọ tí wọ́n wà mu.) 


Àlàyé tí Moronkọ́lá (2002:152) ṣe yìí, ló fún wa ní àǹfààní láti  mọ̀ pé, ewì alohùn tí àwọn Yorùbá máa ń gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọdé kọjá ìgbádùn tàbí eré lásán. Ó níí ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jèrè ọkàn àwọn ọmọ náà lórí òfin, èèwọ̀, àṣà, ẹ̀sìn àti oríṣìí àwọn ìgbòkègbodò wọn mìíràn tí wọ́n fi ń ṣe ètò àwùjọ wọn. Ìdí nìyí, tí a fi gbàgbọ́ pé àṣà kì í kú bọ̀rọ̀. Nítorí pé, Òrìṣà tí a kò bá fi ìdí rẹ̀ han ọmọdé níí parun. Ọ̀nà tí àṣà àti ìṣe àwùjọ kì í sì í gbà parun ni àwọn Yorùbá tọ̀ láti máa fi lítíréṣọ̀ wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn yìí. Èyí gan-an ṣe àfihàn ipa pàtàkì tí lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá kó nínú àmúgbòòrò àṣà, ẹ̀sìn àti àwọn ètò ìgbé-ayé wọn mìíràn.


 Bámidélé (2000:69) tilẹ̀ sọ pé:
The relevance of literature to history is not in doubt but the growth of sociology in the 19th century has introduced a new dimension into the idea of history and literature. History, we often think concerns itself with an account of the biography of monarchs, kings and warriors. Or it is at best an account of the deeds of the ancient. For its style, the business of history is the narration, in a sequential series of events in their connection or coherence with culture as a context.


(Àjọṣepọ̀ tó ń wáyé láàrin lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀-ìtàn-àwùjọ kò rújú rárá, wọ́n jọ ń mú ìdàgbàsókè bá ètò-ìbágbépọ̀ ní Ọ̀rúndún kọkàndínlógún tí ìmọ̀ ọ̀tun ti ṣúyọ nípa lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀-ìtàn-àwùjọ. Ní ti ìmọ̀-ìtàn-àwùjọ, ohun tí a máa ń rò nípa rẹ̀ ni pé, ó níí ṣe pẹ̀lú ètò ìgbé-ayé àwọn Ọba Aládé, àwọn akọni àti àwọn jagunjagun. Tàbí kí á tilẹ̀ sọ pé ó jẹ́ ìlànà tí a fi ń mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀-àtijọ́. Nínú ìṣọwọ́-ṣàgbékalẹ̀ ìtàn, ó jẹ mọ́ ìtàn-rírọ́, ní ìlànà àfihàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn lẹ́sẹẹsẹ, tí ó sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àṣà gẹ́gẹ́ bí ọ̀gangan-ipò rẹ̀.) 


Onímọ̀ yìí fi yé wa pé, inú lítíréṣọ̀ àti ìmọ̀-ìtàn-àwùjọ ni gbogbo àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ kọ̀ọ̀kan láti ẹ̀yìn wá máa ń ṣodo sí. Fún ìdí èyí, a lè sọ pé àrọ́bá ni àwọn ewì alohùn ọmọdé tí wọ́n ń gbé kalẹ̀ láwùjọ Yorùbá jẹ́ fún àwọn ọmọ wọn. Nítorí pé, bí ọmọdé kò bá ìtàn, yóò bá àrọ́bá tíí ṣe bàbá ìtàn. Yàtọ̀ sí èyí, èdè lílò náà jẹ́ èròǹgbà pàtàkì fún àwọn àgbàgbà àwùjọ Yorùbá lórí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ewì alohùn tí wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Wọn a máa fi kọ́ wọn ní àṣà, ìṣe, ẹ̀sìn, ìmọ̀-ìbágbépọ̀, ìmọ̀-ẹ̀dá-èdè, ìmọ̀-ìṣọwọ́lo-èdè àti ìmèdèélò, kí wọ́n má baà máa fi ojo pe Òjó. Bí àwọn ọmọdé sì ti ń dàgbà, ni òye àwọn n̄ǹkan tí wọ́n ń kọ́ wọn yìí yóò máa yé wọn sí i.  


Èyí sì ni ohun tí wọn yóò máa fi ọkàn rò, tí wọn yóò sì máa fi ojú rí, tí wọn yóò máa fi etí gbọ́, tí wọn yóò máa fi ọwọ́ kàn, àti àwọn ohun tí wọn yóò máa ṣe akitiyan oríṣìíríṣìí lé lórí. Ìdí nìyí, tí àwọn agbátẹrù ìfojú-ìmọ̀-ìbágbépọ̀-wo-iṣẹ́-ọkàn tí a lo àfojúsùn wọn fún ìwádìí yìí fi gbà pé, ọkàn ni olúborí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ènìyàn. Bí a bá fẹ́ kẹ́sẹjárí lórí gbogbo ohunkóhun tí à ń ṣe, kí á máa kíyèsí ipò tí ọkàn wa wà. Èyí ni yóò sì fún wa ní àǹfààní láti  máa kópa nínú àmúgbòòrò àwùjọ wa, bí àṣà àwùjọ náà bá ti ń yé wa sí.



1.3 Ọ̀nà tí Àwọn Yorùbá ń gbà kọ́ Àwọn Ọmọ wọn ní Ìwà Ọmọlúàbí
Nínú irúfẹ́ àwọn ewì alohùn ọmọdé tó jẹ mọ́ akitiyan, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọdé ní ìlànà bí a ti ń lo gbogbo àwọn ẹ̀yà ara láti ṣe onírúurú n̄ǹkan. 


Àwọn ewì alohùn yìí ni wọ́n gbé kalẹ̀ láti máa ṣe ìdánwò fún àwọn ọmọdé kí wọ́n lè mọ̀ bí wọ́n bá jẹ́ abarapá tàbí láti mọ̀ bóyá àléébù wà nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ara wọn. Ẹ wo àpẹẹrẹ ewì alohùn yìí ní ilẹ̀ Yorùbá: 
(Taa ló wà nínú ọgbà náà?) 
Lílé: Taa ló wà nínú ọgbà náà?
Ègbè: Ọmọ kékeré kan ni
Lílé: Ṣé a wáá wò ó?
Ègbè: Máà wáá wò ó 
Lílé: Kí ló ń ṣe? 5
Ègbè: Ó ń ṣu
Lílé: Ìwọ lo kọ́
Ìwọ ló mọ̀ ọ́n
Ìwọ ló ṣọ̀bùn lẹ́yìn ọgbà 
Tí ń kó yangan yangan báni lọ́jà 10
Ọmọ bàǹtù tí ń lo ṣííbí 
Ègbè: Tẹ̀ lé mi ká lọ.)
Èyí ń kọ́ àwọn ọmọ náà ní ìlànà tí ènìyàn fi ń lo ọgbọ́n àti òye láti wádìí nípa ohun tí kò yé e. 


Bákan náà ẹ̀wẹ̀, gbogbo ẹ̀yà ara àwọn ọmọ yìí ni yóò máa ṣiṣẹ́ papọ̀ ní àkókò náà, tí ọpọlọ wọn yóò fi jí pépé. Tí a bá tilẹ̀ wo ìlà kẹjọ sí ìlà tí ó kẹ́yìn nínú àyọlò òkè yìí, a ó rí i pé lílé tí aṣáájú eré náà lé ewì náà ń fi hàn pé, wọn kò fi ara mọ́ àwọn ìwà bí ọ̀bùn tí ń dá yánpọnyánrin sílẹ̀ nínú àwùjọ. Èyí ni wọ́n ń tọ́ka sí pé kí wọ́n máa yọ àwọn tí ọwọ́ aṣáájú wọn bá ti tẹ̀ kúrò, pé àwọn tí wọ́n ṣọ̀bùn ni ọwọ́ rẹ̀ tẹ̀ yẹn. Lóòótọ́, kì í ṣe pé àwọn tí ọwọ́ aṣáájú eré náà tẹ̀ ti ṣe ọ̀bùn, ṣùgbọ́n, ohun tí wọ́n fẹ́ kí ó wà lọ́kàn àwọn ọmọdé ni pé, kò dára kí ènìyàn máa ṣe ọ̀bùn. Ènìyàn tí ó bá ń hùwà wọn kì í bá ẹgbẹ́ pé.


Ògúnbọ́nà (2011:39-40) tilẹ̀ sọ pé:
Yorùbá indigenous music can be used effectively as a medium of instruction at the primary level. Health education as a subject in the primary school is meant to sensitize the pupils about those things they should either do or not so as to promote health. When these things are expressed in indigenous songs, it aids the ability of the pupils to recur and remember easily.


(Àwọn orin ìbílẹ̀ Yorùbá jẹ́ èyí tí a lè lò ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a lè gbà kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ètò-ẹ̀kọ́ ajẹmọ́-ìlera gẹ́gẹ́ bí abala ẹ̀kọ́ kan pàtàkì ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó níí ṣe pẹ̀lú ọ̀nà tí a lè gbà kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ohun tí ó tọ́ fún wọn láti ṣe àti àwọn ohun tì kò tọ́, kí ètò-ìlera wọn lè kún ojú òṣùwọ̀n. Bí a bá ń lo irúfẹ́ àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí kókó-ọ̀rọ̀ nínú orin ìbílẹ̀, ó máa ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti tètè rántí wọn dáadáa.)
Èròǹgbà méjì ni onímọ̀ yìí ní lọ́kàn nípa ewì alohùn ọmọdé tí ó pè ní orin ìbílẹ̀ nínú àyọlò òkè yìí. Lọ́nà àkọ́kọ́, ó gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà tí a lè fi kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ ìlera. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ó fi hàn pé ìsọ̀yè ni ọgbọ́n ìforinkọ́mọlẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ fún àwọn ọmọdé.


1.4 Ẹ̀kọ́ nípa Ètò Ọrọ̀-Ajé
Ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó wọ àwùjọ Yorùbá, ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìlànà tí a fi ń ka owó àti ọjà tí à ń tà. Oǹkà (iye) tí wọ́n ń lò, ló fa irú àwọn ewì alohùn tí a rí ní ilẹ̀ Yewa-Àwórì yìí:
(Ká múgbá lámù)
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù.
Ó dení.
Ègbè: Ení bí ení 
Lílé: Ká múgbá lámù 5
Ká fi dámù
Ó dèjì 
Ègbè: Èjì bí èjì
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù 10
Ó dẹ̀ta
Ègbé: Ẹ̀ta ǹ tagbá
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù
Ó dẹ̀rin 15
Ègbè: Ẹ̀rin wọ̀rọ̀kọ̀o
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù
Ó dàrún  
Ègbè: Àrún ń gbódó 20
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù.
Ó dẹ̀fà.
Ègbè: Ẹ̀fà tièlè.
Lílé: Ká múgbá lámù 25
Ká fi dámù
Ó dèje
Ègbè: Olúgbọ́n kìje
Lílé: Ká múgbá lámù 
Ká fi dámù 30
Ó dẹ̀jọ
Ègbè: Arẹ̀sà ṣorò, ó kìjọ
Lílé: Ká le máa jọ 
Ká múgbá lámù
Ka fi dámù 35
Ó dẹ̀sán-án
Ègbè: Ọjà Akẹ̀sán tún disán-òní
Ká máa ríra wa
Lílé: Ká múgbá lámù
Ká fi dámù 40
Ó dẹ̀wá
Ègbè: Àwa ara wa ríra wa ò ò 
Àwa ara wa ríra wa ò ò
Ológìnní rọ́mọ ẹkùn
Àwa ara wa ríra wa ò ò.)  

45
Ìlà àkọ́kọ́ nínú àyọlò òkè yìí fi hàn pé wọn yóò mú n̄ǹkan kan ni. Ìgbá tí wọ́n máa ń fi bu omi mu nínú ìkòkò (àmù) ni wọ́n tọ́ka sí. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ náà ni, bí a ti ń yára ṣe ohun tí a bá fẹ́ ṣe ní kíá kíá, yàtọ̀ sí pé wọn yóò máa ka oǹkà tó hàn ní ìlà kẹta, ìlà keje, ìlà kọkànlá, ìlà kẹẹ̀ẹ́dógún, ìlà kọkàndínlógún, ìkẹtàlélógún, ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n, ìkọkànlélọ́gbọ̀n, ìkẹrìndínlógójì, àti ìkọkànlélógójì. Ẹ̀kọ́ nípa bí a ti ń ṣùwàpọ̀ láti rí ara ẹni bí mọ̀lẹ́bí àti alájọṣepọ̀ ló hàn ní ìlà kejìlélógójì sí ìlà karùndínláàádọ́ta àyọlò yìí. 


Gbogbo akitiyan yìí yóò máa jẹ́ kí àwọn ọmọ náà lo ojú, ìka ọwọ́, apá, ẹsẹ̀, ọkàn àti ọpọlọ àti àwọn ẹ̀yà ara wọn yòókù papọ̀ láti tètè mọ iye n̄ǹkan tí wọ́n ń kà náà. Ẹ̀kọ́ ìṣirò ìbílẹ̀ Yorùbá gba ìrònújinlẹ̀ tó péye. Wọ́n ń lò ó fún kíka onírúurú n̄ǹkan bí owó, ọjà tí wọ́n ń tà, àkókò àti ọjọ́. Irúfẹ́ ìlànà yìí náà wà nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò ti ètò-ẹ̀kọ́ ìgbàlódè. 


Nítorí náà, ọkàn wọn ni yóò máa dárí gbogbo ẹ̀yà ara wọn yìí nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ oǹkà kíkà náà. Ìrètí wọn ni pé, dandan ni kí àwọn ọmọ náà lè mọ̀ nípa ètò ọrọ̀-ajé àwùjọ wọn dára dára, bí wọ́n bá ti ń fi ọkàn bá irúfẹ́ ewì alohùn òkè yìí lọ. Èyí tilẹ̀ hàn ní ìlà kẹtàdínlógójì sí ìlà kejìdínlógójì nínú àyọlò náà. Ọjà kan tí ó gbajúmọ̀ ní ayé-àtijọ́ ni wọ́n ń pè ní ọjà Akẹ̀sán. 


Ó hàn nínú àyọlò náà ní ìlà kẹtàdínlógójì pé ọjọ́ mẹ́sàn-án síra ni wọ́n ń ná ọjà Akẹ̀sán nígbà náà. Èyí ni wọ́n pè ní Isán. Bákan náà sì tún ni ìlú kan wà ní ilẹ̀ Àwórì ní ìlú Èkó, tí ń jẹ́ Àkẹ̀sán. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìlú yìí gan-an ló hàn nínú àyọlò yìí tàbí ọjà Akẹ̀sán tí ó wà ní agbègbè Èjìgbò.
1.5 Ẹ̀kọ́ nípa Àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwùjọ
Àwọn ohun ìṣèǹbáyé àwùjọ kọ̀ọ̀kan káàkiri àgbáyé ni a lè tọ́ka gẹ́gẹ́ bí ogún fún àwọn ọmọ àti àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àtúntò, àtúnrọ àti àgbéjáde ìmọ̀ ọ̀tun tí àwọn ọmọ àti àrọ́mọdọ́mọ ìran kọ̀ọ̀kan náà bá ń ṣe sí àwọn ohun àjogúnbá wọn, ni yóò máa mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ bẹ́ẹ̀. Ìṣọ̀lá (2009:93) sọ pé:
Our cultural heritage has the tangible and intangible components. 


The tangible heritage refers to those things that have physical form like carved wood and calabashes, statues, drums, costume, historical landscapes and site, buildings, monuments and so on. The intangible components are those aspects that have no physical form, like our language and literature, oral traditions, customs, music, rituals, festivals, and other special skills. 


The … fact,… is that it is the intangible component of cultural heritage, where literature is dominant, that sustains the tangible aspect because it is the source of those valuable ideas like dignity, hope sense of duty, acceptable standard of right and wrong, hardwork, faithfulness, accountability, honour, fraternity and other humane qualities.


(Àṣà àti ìṣe ìbílẹ̀ wa ṣe àkóónú àwọn ohun-èlò àfojúrídìmú àti àwọn ohun-èlò àìrídìmú. Àwọn ohun-èlò ajẹmọ́-àṣà àfojúrídìmú wọ̀nyí ń tọ́ka sí àwọn n̄ǹkan tí a lè fi ojú wa rí tí a sì lè fi ọwọ́ wa kàn wọ́n bí ọnà-igi gbígbẹ́ àti àwọn igbá fínfín, àwọn ère lóríṣìíríṣìí, àwọn ìlù lóníran-án-ran, àwọn ohun-èlò ìṣèré, àwọn ilẹ̀ àti ohun-àlùmọ́nì wọn ti ìtàn àtayébáyé, àwọn ẹ̀yà ilé kíkọ́ lóríṣìíríṣìí, àwọn ohun-ọ̀ṣọ́-ara àti àwọn n̄ǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀. Àwọn tí a kà kún ohun-èlò ajẹmọ́-àṣà ní abala ti àìrídìmú ni àwọn n̄ǹkan tí a kò lè fi ojú wa rí, tí a kò sì lè fi ọwọ́ wa kàn, bí àwọn èdè wa àti ìpohùn, ìtàn rírọ́, àṣà, tìlùtìfọn, ètùtù ṣíṣe, ọdún ìbílẹ̀, àti oríṣìí n̄ǹkan ajẹmọ́-àṣà mìíràn. Ohun… tí… ó ṣe pàtàkì ni pé, àwọn ohun-èlò ajẹmọ́-àṣà ti àìrídìmú wọ̀nyẹn, ni òpómúléró fún àwọn ohun-èlò ajẹmọ́-àṣà ti àfojúrídìmú, ní èyí tí lítíréṣọ̀ jẹ́ olúborí fún wọn, nítorí pé àwọn gan-an ni orísun fún àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì bíi ọmọlúàbí, ìnírètí, ọgbọ́n ìmúṣẹ́ṣe, mímọ òfin àti èèwọ̀ inú àwùjọ, ìṣe akin, òtítọ́ ṣíṣe, ojúṣe-àìṣẹ̀tàn, ìbọláfúnni, ẹgbẹ́ ọ̀gbà àti àwọn ìwà ọmọlúàbí mìíràn.)


Gbogbo ohun tí a ní lọ́kàn, tí a fi ṣe ìwádìí nípa ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tí àwọn Ẹ̀gbá, Yewa-Àwórì àti àwọn Ìjẹ̀bú máa ń fi kọ́ ọmọ wọn ni Ìṣọ̀lá (2009:93) ṣe àfihàn rẹ̀ nínú èrò rẹ̀ yìí. Tí a bá tilẹ̀ wo àtòjọ àwọn ohun tí onímọ̀ yìí tọ́ka wọn pé lítíréṣọ̀ ni òpómúléró fún wọn, a óò rí i pé, ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú èròǹgbà fífi ewì alohùn ọmọdé kọ́ àwọn èwe ní àṣà àti ìṣe àwùjọ. Èyí ni àfojúsùn àwọn agbátẹrù ìfojú-ìmọ̀-ìbágbépọ̀-wo-iṣẹ́-ọkàn tí a fi  ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò ewì alohùn ọmọdé ti ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú àti ti àwọn Yewa-Àwórì.


Ìpele tí àwọn onímọ̀ ajẹmọ́-iṣẹ́-ọkàn ti rí ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí aláròjinlẹ̀ nípa àwọn ohun tó ṣodo sí àyíká wọn láti máa fún àwọn n̄ǹkan náà ní ìtúmọ̀ kíkún ni abala yìí jẹ mọ́. Nínú àwùjọ àwọn Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú àti ti àwọn Yewa-Àwórì, a ṣe àkíyèsí pé wọ́n ṣe àtòjọ àwọn ewì alohùn tí wọ́n ṣẹ̀dá fún àwọn ọmọdé ní ìpelejìpele láti máa fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó wà ní àyíká wọn ni. Wọ́n ṣe èyí, kí ìrònú àwọn ọmọ náà lè jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n ń fi ojú rí, tí wọ́n ń fi etí gbọ́, tí wọ́n ń fi ọwọ́ kàn, tí wọ́n sì ń fi ọkàn rò. 


Èyí ni àkíyèsí tí àwọn onímọ̀ ajẹmọ́-iṣẹ́-ọkàn pè wá sí nípa ìlò ẹ̀yà ara láti gbé òye, ìmọ̀ àti ọgbọ́n yọ nípa ohun tí à ń fi ọkàn rò. Ọ̀pẹ́fèyítìmí (2013: 136) tilẹ̀ sọ pé:
… thinking (rò) is the basic input or raw material of production, so to say, in the industrial house of the brain. A future collaboration with psychiatric surgeons, I believe, will yield some proper findings, especially on the appropriate medical nomenclature for each “machinery” of the brain involved in each stage.


(…ìrònú tí (rò) jẹ́ òpómúlé tàbí èròjà pàtàkì nínú àgbéjáde èrò, tí a lè fọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà, nínú agbami èrò-ọkàn. Ọjọ́ iwájú tí à ń fojúsùn ní agbo àwọn onímọ̀ nípa àrùn-ọpọlọ, ni mo gbàgbọ́ pé, yóò mú àkọ̀tun ìwádìí tó múná dóko wáyé, pàá pàá jù lọ lórí ìlànà tó mọ́yán lórí fún àwọn oníṣègùn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan “àwọn-èròjà” tó ń kópa nínú ọpọlọ ní ìpele kọ̀ọ̀kan).


Àrífàyọ wa nínú àkíyèsí onímọ̀ yìí nípa ìṣẹ̀dá ewì alohùn ọmọdé ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú àti ti àwọn Yewa-Àwórì ni pé, inú ọpọlọ ni ìrònújinlẹ̀ ti ń sun jáde wá. Ọpọlọ àwọn ènìyàn náà sì ní àwọn-èròjà tó so mọ́ ọn ní ìpele ìpele. Ẹ wo àpẹẹrẹ ewì alohùn yìí:
(Mo pàdàbà lábàa bàbá
Bàbá Alábà bá mi mádàbà lábà
Mo sàdàbà lábàa bàbá Alábà
Mo jàdàbà lábàa bàbá Alábà
N ò bun bàbá Alábà ládàbà jẹ.)


Àkóónú ewì akọ́nilẹ́nu tó wà lókè yìí ni ẹ̀kọ́ nípa èdè pípè, ìwà ọmọlúàbí, iṣẹ́ ọdẹ ṣíṣe, àṣà ìranra-ẹni-lọ́wọ́ àti ìbọ̀wọ̀fágbà. Ní ìlà àkọ́kọ́, wọ́n fi iṣẹ́ àwọn ọdẹ apẹyẹ hàn níbẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ ni ẹyẹ àti eku pípa. Kedere sì ni àṣà wọn yìí hàn nínú àyọlò òkè yìí. Àwọn ọmọdé ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ ọdẹ ẹyẹ pípa àti eku. Tí a bá wo ìlà kejì àyọlò òkè yìí, a ó rí i pé, wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ ìranra-ẹni-lọ́wọ́ pé ohun tí agbára wọn kò bá ti ká, kí wọ́n máa fi lọ àwọn àgbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn onímọ̀ ìfojú-ìmọ̀-ìbágbépọ̀-wo-lítíréṣọ̀ gbà pé, bí àwùjọ bá ṣe la àjùmọ̀ṣepọ̀ wọn kalẹ̀, ni yóò mú àṣeyọrí bá wọn lórí ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Bákan náà sì ni èrò àwọn onímọ̀ ajẹmọ́-iṣẹ́-ọkàn fi hàn pé àwùjọ máa ń gbin àwọn ìwà kan sí àwọn ọmọdé lọ́kàn, tí yóò ní ipa lórí ètò ìgbé-ayé wọn.


1.6 Àgbálọgbábọ̀ 
Ṣáájú kí ìmọ̀-mọ̀-ọ́n-kọ- mọ̀-ọ́n-kà tó wọ àwùjọ Adúláwọ̀ lápapọ̀ ni àwọn Yorùbá ti ní ìlànà tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́-ilé tí yóò sọ wọ́n di ọmọlúàbí nínú ètò àwùjọ wọn. A ṣe àkíyèsí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ pàtàkì mẹ́wàá nínú ètò-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé ní orílẹ̀-èdè Náìjíríà lápapọ̀. Èyí ni a rí òye wọn nínú ìlànà ètò-ẹ̀kọ́ ìbílẹ̀ àwọn ẹ̀yà Yorùbá yìí. Àwọn kókó-ọ̀rọ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni Èròǹgbà-ẹ̀kọ́, Ilé-ẹ̀kọ́, Olùkọ́ni àti akẹ́kọ̀ọ́, ọgbọ́n ìkọ́ni, Ohun-èlò ìkọ́ni, Yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, Kókó-ẹ̀kọ́, Àtẹ-iṣẹ́, Àbájáde-ètò-ẹ̀kọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè. Gbogbo àwọn kókó-ọ̀rọ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí ló ní ipa lórí ètò ìgbé-ayé àwọn Yorùbá nínú àwùjọ wọn.


Èròǹgbà-ẹ̀kọ́ ni ṣíṣe àgbékalẹ̀ ètò kan pàtàkì láti lè fi darí ojú-àmúwayé àwùjọ kan, kí àṣeyọrí lè bá wọn nínú gbogbo ohun tí ó rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ àti ìkọ́ni nínú àwùjọ bẹ́ẹ̀. Olúborí èròǹgbà àwọn Yorùbá nínú ètò-ẹ̀kọ́ wọn ni ẹ̀kọ́ ìwà ọmọlúàbí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn. Èyí ló ṣe okùnfà àgbékalẹ̀ àwọn ewì alohùn ọmọdé tí ó jẹ mọ́ ètò-ìlera, ètò ọrọ̀-ajé, ètò-ìṣèlú, ìkọ́nilédè, ìkọ́niláṣà, ìkọ́ni-ní-ìbágbépọ̀, ìkọ́nilẹ́sìn, àti onírúurú ẹ̀kọ́ mìíràn tí ń sọ ènìyàn di ọmọlúàbí nínú àwùjọ rẹ̀. 


Bí a bá sì wo èròǹgbà àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí a ṣe ìwádìí nínú àwùjọ wọn yìí, a ó rí i pé èròǹgbà wọn náà wà ní ìbámu pẹ̀lú ti Àjọ-Alábòójútó Ètò-Ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà lórí ètò-ẹ̀kọ́. Àwọn èròǹgba tí Àjọ-Alábòójútó Ètò-Ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà gbé kalẹ̀ nìyí:
Education would continue to rank high in the nations’s development plans. Education is the most important instrument of change and any fundamental change in the social and intellectual outlook of any society has to be preceded by education. (Ètò-ẹ̀kọ́ yóò túbọ̀ máa gbèrú sí i láti mú kí ètò àwùjọ Nàìjíríà lè kẹ́sẹjárí. Ohun-èlò pàtàkì jù lọ ni ètò-ẹ̀kọ́ jẹ́ fún ìyípadà, ní èyí tí ó sì já sí pé, gbogbo ìyípadà rere nínú ètò-ìbágbépọ̀ àti ẹ̀kọ́-ìmọ̀ nínú àwùjọ ni ojúṣe ètò-ẹ̀kọ́.)


Education activities would be centered on the student for maximum self-development. (Akitiyan ètò-ẹ̀kọ́ yóò dá lórí fífi àyè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀kọ́ láti lè jẹ́ kí wọ́n ní òmìnira ìdàgbàsókè-ara-ẹni.)


Religious studies shall be introduced into the program of Universal Basic Education (UBE) to foster societal faiths and beliefs of the nation into the citizen. (Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn yóò pọn dandan nínú abala ẹ̀kọ́ (UBE) lati jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti èrò-ìjìnlẹ̀ àwùjọ wọn.)


At all levels of education, the societal needs shall be excepted as their output on socio-economy, socio-cultural and socio-political. (Àfojúsùn àwùjọ lórí ọrọ̀-ajé, àṣà àti ìṣèlú yóò wà ní gbogbo ìpele ètò-ẹ̀kọ́.)
Physical and health education shall be emphasized at all levels of the education system. (Ètò-ẹ̀kọ́ ajẹmọ́-ìlera yóò wà ní gbogbo ìpele ètò-ẹ̀kọ́.)


The national education system shall be structured to develop the practice of self-development in craft and trades. (Ìlànà ètò-ẹ̀kọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò di àtúntò nípa fífi wo ọ̀nà tí ẹnìkọ̀ọ̀kan le fi mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ iṣẹ́-ọwọ́ àti okòwò ṣíṣe.) 


Gbogbo àwọn kókó-ọ̀rọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí a tò jọ sókè yìí ni èròǹgbà ètò-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé ilẹ̀ Nàìjíríà lápapọ̀. Kò sí èyí tí kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí àwọn Yorùbá ń lo ewì alohun ọmọdé láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ṣáájú ìmọ̀-mọ̀-ọ́n-kọ-mọ̀-ọ́n-kà. Kí ohun tí à ń wí nípa onírúurú ọ̀nà tí àwọn Yorùbá ń gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lè yé wa, ẹ wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí:
                                           

          Lítíréṣọ̀ Ọmọdé

1.        Lítíréṣọ̀ Alohùn ọmọdé         2.     Lítíréṣọ̀ Àpilẹ̀kọ ọmọdé



1. Lítíréṣọ̀ Alohùn ọmọdé


Ewì Alohùn ọmọdé        Ìtàn Àròsọ-ọlọ́rọ̀- geere ọmọdé     Eré-Oníṣe ọmọdé  
 Ajẹmọ́-ẹ̀sìn Ìbílẹ̀                Àlọ́ onítàn          Ẹkẹ jíjà
 Orin Àlọ́               Àlọ́ Onítàn Aláìlórin          Eré-òṣùpá 
 Àlọ́ Àpamọ̀                        Ìtàn Fèyíkọ́gbọ́n                              Eré-Ojúmọmọ    
 Ewì Akọ́nilẹ́nu            Ìtàn Fèyíkọ́gbọ́n Alálọ̀ọ́
 Orin Eré Ojúmọmọ            Ìtàn Fèyíkọ́gbọ́n Arúmọlójú
Orí Eré Òṣùpá                     Ìtàn Apanilẹ́rìn-ín     
 Ewì Onítàn  
  Orin Ajẹmọ́-Àríyá
 

2. Lítíréṣọ̀ Àpilẹ̀kọ ọmọdé


 Ewì-Àpilẹ̀kọ                             Eré-Onítàn                        Ìtàn-Àròsọ 
  Àwọn Ewì Ọdúnjọ
   Àwọn tó jẹ mọ́ ti Ọdúnjọ          Àwọn ìwé
   Ewì Ìgbàlódé           Ìtàn-Àròsọ kúkúrú



Fig. 1: Àtẹ Aṣàfihàn Ìpínsísọ̀rí Lítíréṣọ̀ Ọmọdé

Ìwé-Ìtọ́kasí
Abímbọ́lá, W. (1977). Àwọn Ojú Odù Mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún. Ìbàdàn: Oxford University Press.
Adéoyè, C.L (1979). Àṣà àti Ìṣe Yorùbá. Ìbàdàn: Oxford University Press.


Bámidélé, L. O (2000) Literature and Sociology, Lagos. Stirlig-Horden Publishers Nig. 
Ìdòwú, E.B. (1962). Olódùmarè: God in Yorùbá Belief, London: Longmans.


ÌṢỌLÁ, S. A. (2006): “Ìjẹyọ Èrò àti Ìgbàgbọ́ Àwọn Yorùbá Nípa Ìlò Oògùn Nínú Ìwòsàn Ìbílẹ̀ Ṣíṣe” (N.C.E Project, TASUED Ìjẹ̀bú-Òde). 
ÌṢỌLÁ, S. A. (2015): “Yorùbá Verbal and Non-Vebal Communication as a Tools for Cultural Development: Enhancing the Western Educational System in Yorùbá Society” in ZUBA JOURNAL OF LANGUAGES. Àbújá, School of Languages, FCT College of Education, Zuba-Àbújá.


ÌṢỌ̀LÁ, A. (1996). “Forms of Dramatic Language in Yorùbá Literature” nínú Ọlátúnjí, Ọ. (ed.). The Yorùbá History, Culture & Language. Ìbàdàn: UPL. O.i 97-146.


ÌṢỌ̀LÁ, A. (2009). “Yorùbá Culture in Education” nínú Ògúndèjì, A. àti Àkàngbé, Adéníyì (ed.). ỌMỌLÚÀBÍ: Its Concept and Education in Yorùbá Land. Ìbàdàn: Ìbàdàn Cultural Studies Group. O.i89-112. 


ÌṢỌ̀LÁ, S. A. (2014), “Àgbéyẹ̀wò kókó-ọ̀rọ̀ àti Ìṣọwọ́lò-Èdè Nínú Àṣàyán Ewì Alohùn Yewa-Àwórì” B.A. Long Essay Department of Linguistics and African Languages. O.A.U Ilé-Ifẹ̀.
Moronkọ́lá, M. (2002). “Yorùbá Traditional Physical and Health Education for Natural Development” nínú Ọ̀jẹ́lábí, O.A Physical and Health Education in Nigeria. Lagos. Tomtak Printing Press.


Ògúnbọ́nà, J. A. (2011). “Yorùbá Traditional Health Education” nínú Journal of Physical and Health Education Association of Nigeria. Vol. 4, no. 3, o.i 87-124.


 Òjó, A. (1978). “Ìwà Ọmọlúàbí” nínú Ọlájubù, O. (ed.) Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbáa. O.i. 18-22.
Ọ̀pẹ́féyìtímì, J. A. (2013), “The Articulation of Knowledge, Insight and Wisdom in English and Yorùbá Poems” Winneba, Ghana: nínú Journal of African Cultures and Languages. Vol o2, issue 01, January o.i. 132-141.

No comments

After Dropping your comment, Wait for few minutes, your comments will appear below!!!