BREAKING NEWS

ÌTÀPÒRÓGAN OLÚWÒÓ ÀTI AGBOWÚ ÌṢẸ̀LẸ̀ MÁNIGBÀGBÉ ÒUN ÀPÉRÒ LÁÀÁRÍN ỌMỌ ODÙDUWÀ NI ỌJỌ́ ẸTÌ ỌJỌ́ KẸRÌNLÁ OṢÙ KEJÌ ỌDÚN UN 2020

Eyín ká ilé ẹ̀rín wó àfèrèmọ̀jò kú tán ẹnu isà ń ṣọ̀fọ̀, ọsán já ọrún dọ̀pá, bẹ́ẹ̀ lẹni a gbójú okùn lè ó jẹni agba. Káàsà!! Ọmọ tán lára ọmọ ti ń jeérú, Voice air media.

OLÚWÒÓ ÀTI AGBOWÚ

_Ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù èrèlè ọjọ́ burúkú èṣù gbomimu, ọjọ́ọ mánigbàgbé nínú ìtàn àwọn ọba aládé méjì láti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí a mọ̀ sí ìpínlẹ̀ ọmọlúwàbí àti orírun gbogbo ìran ọmọ Odùduwà níbi tí Olúwòó tìlúù Ìwó ti kó ìgbátí olóòyì bo Kábíèsí *Agbowú* tìlúù Ọ̀gbáàgbà tó mú kójúu Kábíèsí pọ́n fò.


Ibi àpérò kan ni mo wa nílùú "Èkó" ṣà dédé ni aago ìléwọ́ mi pariwo síta gbogbo ènìyàn tó wà nínú gbọ̀ngàn ìpàdé náà ló dojú bòmí, kò sì ṣíṣe kò sàì ṣe mo ṣáà fìtìjú gbé aago lẹ́yìn ìpè ẹlẹ́ẹ̀kẹfà nítorí mi ò mẹni náà tô ń pèmí lemọ́lemọ́ àti pé mi ò mọ bi ìpè náà ṣe ṣe pàtàkì tòó; n lẹni náà ń bá mi sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ mo ni kò gbóùn sókè kò pẹ́ rárá mo ni láti tọrọ ààyè láti jáde kúrò nínu gbọ̀ngàn àpérò láti fetí gbọ́ ohun tí ẹni náà fẹ́ ẹ́ sọ nítorí òhún ẹni náà jọ tẹni tó fẹ́ tamílólobó ohun pàtàkì kan.


Ohun tí alamí náà sọ ni pé ó tún ti bẹ̀rẹ̀ ooo lẹ́ẹ̀mejì. Mo ni tani?


Alamí ni Kábíèsí Olúwòó ni o. Mo ni  Kábíèsí Olúwòó bí i ti bóo?


Kílóṣe Olúwòó nìbéèrè tó tún jáde lẹ́nu mi?

Alamí ní ìtàpòrógan ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láàárín  Olúwòó àti Ọba Agbowú nínú ọ́fíìsì Ọ̀ga ọlọ́pàá àgbà AIG ni ìlú Òṣogbo ìyẹn, (zone 11).


Mo ni kí ló fa jẹ̀jẹ̀tì, fàákája òun ìrégbè láàárín ọba aládé méjì lásìkò ti Yorùbá nílò "ÌṢỌ̀KAN" nílẹ̀ yìí?


Alamí ni ọ̀rọ̀ èmí jùọ́, ìwọ ò jùmí àti ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ló fa fàákája tí ọ̀ga ọlọ́pàá, àwọn olóṣèlú, ọ̀tọ̀kùlú ìlú àti àwọn orítiadé mìíràn wà níkàlẹ̀ láti pẹ̀tù sí aáwọ̀ ọ̀hún nítorí fàákája náà ti wà nílẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn láàárín àwọn ọba méjèèjì nítorí àńjùwọ́n ò ṣé wí lẹ́jọ́ ìjà ìlara kò tàn-án bọ̀rọ̀. kọ́rọ̀ ọ̀hún tó ó búrẹ́kẹ́ níbi tí "Ọba Abdul Rasheed Àkànnì Telú àkọ́kọ́" Olúwòó tìlúù Ìwó tí dìde gba Agbowú ti ìlu Ọ̀gbáàgba létí Ọba Dikrullai Ọlálékè Akínrọ́pò, Ọlábíran.


Káàsà!!! ni mo dáhùn imí ẹran nídìí èèyàn kí ọba aládé máa gbá ọba aládé ẹgbẹ́ ẹ̀ létí láyé ọ̀làjú yìí.


Mo ni págà!! Èèmọ̀ rèé nipìínlẹ̀ Ọ̀ṣun èṣù láàlú ògiri òkò, ẹlẹ́kún ń sunkún láaroyé ń sẹ̀jẹ̀.


Níbi tí orí adé ti ń fi ara wọn ṣẹ̀sín lójú aráyé, níwájú àwọn màjèṣín, òun gàǹbàrí.


Orí adé wá dẹni yẹpẹrẹ, àwọn ẹni àpọ́nlé wâ dẹni àá fẹnu àbùkù kàn lójú ọ̀pó ẹ̀rọ ayélujára (social media).


Tógún bá jẹlọ, ọgbọ̀n ń jẹ padà bọ̀ dandan ni.

Ìròyìn tí a ri gbámú ni pé Agbowú ti ìlú Ọ̀gbáàgbà niwọ́n ti jọ ní èdèàìyedè nílẹ̀ pẹ̀lu Káábíèsí Olúwòó lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí àwọn ìjọba àti ọ̀ga ọlọ́pàá pè wọ́n sípàdé àpérò láti jÓgunómí láàrín àwọn méjèèjì kàkà kí kálúku wọn tidà bàkọ̀ níṣe làwọn ọba aládé bẹ̀rẹ gídígbò ti wọ́n wá dẹni àá rámú lỌ́tùn-ún lósì níwájú ọ̀ga ọlọ́pàá AIG.


Ohun àrígbámú mìíràn ni pé Olúwòó ni òun kìí ṣe ọba onípò kan náà pẹ̀lu Agbowú nítorí bàba ńlá wun ló ni ilẹ̀ ti Ọ̀gbáàgbà wà dòní níbi tí Agbowú jọba sí àti pé abẹ́ ìṣàkóso àti ìjọba òun ni Agbowú wà.


Kí wá lódé ti wọn ò ṣe gba àlàáfíà láàyè, na sùúrù sí ọ̀rọ̀ náà tàbí kí wọ́n gbé ọ̀ràn náà lọ sílé ẹjọ́?_ _Èyí ni ìbéèrè tí èmi n bi Alamí kí ọ̀rọ̀ tó wá di fọ́pomọ́yọ̀ nítorí ìkà kọ́ ló máa rojọ́ tó tún máa dáa.


Àsìkò tó láti já pẹ́tẹpẹ̀tẹ ọ̀rọ̀ lulẹ̀.

Kí la gbé ki lajù gan-an ná, níbo là ń lọ nílẹ̀ yìí tá ò rọ́kọ̀?


Tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ gbogbo kìí sé lórí alábaun?

Kí ọba aládé máa yọ "🥊ẹ̀ṣẹ́" sí ọba ẹgbẹ́ ẹ̀ láyé òde òni láì ṣe Anthony Joshua.


Nígbà ti ọba bá ti ń fojú egbò tẹlẹ̀ ńkọ́?

TỌ́ba ò bọ̀wọ̀ fúnṣẹ̀ṣe, fórí àpèrè mọ̀ọ́, nítori tẹ̀sìn àjèjì.


Kí orí-adé kan máa pe ara rẹ̀ ni "Emir." Ǹjẹ́ ọba kan ni ilẹ̀ lárúbáwá tàbí ní ilẹ̀ awùsá/fúlàní pé ara rẹ̀ ni ọba/kábíèsí tàbí kó wá lórí àpèrè/ìgúnwà ọba pẹ̀lú adé ìṣẹ̀ǹbáyé lórí? Kámári ni pọ́ọ̀lù wí.


Mo lérò pé èyí ló fa rúdurùdu tó ń fojoojúmọ́ wáyé yìí láàárín àwọn ọba aládé nítorí àwọn àgbà sọ wí pé "ẹni tó bá ń yọ́lẹ̀ ẹ́ dà ohun abẹ́nú á máa yọ́rú u wọn ṣe."


Ṣé àwọn ẹni táyé ń wò táwọn fúnrara wọn ń wòran, ayé ń tìwọ́n sójú ọ̀nà wọ́n tira wọn sínú igbó orí adé wa dẹni à ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí.


Ọ̀pọ̀ ọba ilẹ̀ kóòótù-oò-jíire ni ò yẹ nípò ọba ṣùgbọ́n púpọ̀ àwọn afọbajẹ ti gbàbọ̀dè wọ́n pe ifá lékèé wón pÒòṣà lólè nítorí owó, púpọ̀ náà tún ni àwọn olóṣèlú àsìkò yìí ń ṣe lọ́rọ̀ ilẹ̀ yìí láti lò agbára yan ààyò ọkàn wọn sípò tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀tá fún ìlú. Báwo ni irúfẹ́ ọba bẹ́ẹ̀ yóò ṣe dÓrí àléfà ọba tí kò ni ṣìwàwù?


Igbá kígbá ni ọ̀pọ̀ ọba gbé nigbà tó wà "nípèbí" tí àwọn olubi afọbajẹ sọ igbá ogun di igbá oyin mọ́ wa lọ́wọ́ nítorí tí wọ́n ti jẹ dòdò ẹnu wọn ò sì gbòdodo mọ́.


Ǹjẹ́ tỌ́ba kan bá gbégbá oyin ní tòótọ́ ṣówá yẹ kí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun abẹ́lé tún máa fojoojúmọ́ wáyé láàárín ọba aládé nílẹ̀ Yorùbá?


Kí gbogbo lỌ́ba lỌ́ba, níjòyè níjòyè lọ sinmẹ̀dọ̀ nítorí ogun ò dàbi iyán o. Àwọn tí ogun "Jálumi, Àdùbí, Kírìjí, Ìdàhọ̀mí,  Ìjàyè........" ṣojú u wọn niwọ́n lè ròyìn fáráyé o, kí gbogbo ìran ọba aládé tètè lọ sagbéjẹ́ mọ́wọ́ ká bójútó iná ètò ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá, iná tó ń jówa lábẹ́ aṣọ lórílẹ̀-èdè yìí. Kìí ṣe kí ọba máa bárawọn jà kọ́ lótọ́.


Àsìkò ìjà, Ìtàpòrógan, ààlà ilẹ̀, ìṣi agbára lò kọ́ ní Yorùbá wà yìí o bikòṣe àsìkò ti kóówá ni láti fìgbànú kan ṣọ̀já káa lè borí ogun tó ń fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ sọwá dèrò ẹ̀yìn lórílẹ̀-èdè yìí. Atbbl.


Odùduwà atẹ̀wọ̀nrọ̀, ọbàtálá ọbàtáàsà, ọba takuntakun lóde ìrànjé gbogbo orí adé ilẹ̀ Yorùbá, ẹ̀yin olóyè,  alálẹ̀ ilẹ̀, ẹ̀yin àgbààgbà mẹ́rìndínlógún tẹ̀ ń bẹ lÓtù ifẹ̀ ńkọ́ níbo ni gbogbo yin wà?


Ẹ má mà sun àsùnpiyè o. Àsìkò ti Yorùbá ń gbèrò láti jàjàbọ̀ lọ́wọ́ ogun àwọn fúlàní lèyìí tó yẹ ki gbogbo orí adé nílẹ̀ kóòótù-oò-jíire fìmọ̀ṣọ̀kan kan ni àwọn kan wà ń tẹrẹ̀fọ̀ bá ìran Yorùbá nílẹ̀ yìí, àti ní gbogbo àgbáyé nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan
"ILÁ TÓ BÁ MỌ NÍWỌ̀N LÀ Ń RẸ́LÁ SÍ O."


Kò sí báa ti máa porí ajá tá ò ni porí ìkòkò táa fi sèé, kí gbogbo àwọn tó ba mọ àwọn ọba wọ̀nyí  báwa bá wọn sọ̀rọ̀ nibi tó yẹ kí wọ́n ti gbọ́, kí wọ́n yé e fi rẹ́dẹrẹ̀dẹ rá àwa ọmọ aládé yòókù lára mọ́ ọ.


Mí ò dẹ̀ mọ̀ bóyá èpè àwọn ọ̀ta Yorùbá ló fẹ́ máa ja àwọn ọba wa ti ìjà ìlara ṣe wá wọ́pọ̀ tó báyìí láàárín wọn.


Ẹnu ọba ilẹ̀ Yoòbá ò kò nípa àwọn ìtàn àdáyébá burúkú mìíràn tí wọ́n ṣì ń gbé kiri ìgboro ayé tí kò lè mú ìrẹ́pọ̀ tàbí ìdàgbàsókè bá wa láéláé Tó dẹ̀ jẹ́ wí pé tá a bá ní ká ka ẹrú inú ẹrú á bàjẹ́, ìjà àgbà láàárín ládéládé nílẹ̀ yìí ó yẹ kó ti ròkun ìgbàgbé.


Ẹ̀yin lónìí ẹ̀yin lọ́la bí ẹkún a pọkọ jẹ, òní agẹmọ kú sáàrò, ọ̀la agẹmọ kú sáàrò ṣé tójú ò bá tAgẹmọ ṣé kò yẹ kójú ti ààrò ní?_  _Kí òwe yìí máa jẹ́ tỌba táje ìwà ìbàjẹ́ bá ṣímọ́ lórí.


Gbogbo ìran Yorùbá lẹ tàbùkù bá ti ẹ sì ni láti "TÚÚBÁ" fún gbogbo ọmọ aládé gbogbo nílẹ̀ yìí àti lókè òkun.


Ìmọ̀ràn fún àwọn aláṣẹ/ìjọba àti àwọn afọbajẹ:
Ẹ̀yin àgbà ní táa bá táa níṣe làá tọ̀ọ́ tá ò bá tọ̀ọ́ yóò padà dẹran onídin ni o.


Kó má ba à wá má dẹran onidin ìdájọ́ òdodo ni láti fìdí múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí nítorí ọba lọ́la náà ń wo ṣààkun ọ̀rọ̀ lónìí.


Ọ̀rọ̀ ń gbé mi nínú, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ò ní gbẹ́nú mi rà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ láéláé.


Ó wuni ká jẹran pẹ́ lẹ́nu òǹfà ọ̀nà ọ̀fun ni ò jẹ̀ẹ́._ _Ṣùgbọ́n àwọn àgbà ni táa bá gé ọ̀ọ̀kùn jẹ pàrà wọ́n ní kí tinú máa gbénú ki tòde máa gbóde, àti pé eégún tó bá pidán mọ níwọ̀n ló ń pidán an pẹ́......_ . _Ọ̀rọ̀ yìí tí tó àpérò ọmọ meríwo.

Ṣé kí á wá ti ọba aládé mọ́lé ni àbí àwọn gan-an ò mọ̀ pé ìjìyà wà fún ìwà a abanilójújẹ́ yìí ni? Nítorí òkùnkùn ò mẹni ọ̀wọ̀ lọ̀rọ̀ òfin ilẹ̀ yìí o, idà olójú meji sì ni pẹ̀lú.


Ó TÚN DÌGBÀ KAN NÁ....

Èmi náà lọmọ asunkun gbadé, afọ̀rọ̀ gboyè àtẹ́wọ́ méjèèjì la fi ń gboyè nílé tiwa, ọmọ òwu ti kìí ránró àwíìmẹ́nu kúrò ní tÒwu.


_Èmi ni tí yìí ni tòót ONÍṢỌ̀KAN
ẸGBẸ́ ÌṢỌ̀KAN ỌMỌ ODÙDUWÀ FOUNDATION®  (ISOOF)"

No comments

After Dropping your comment, Wait for few minutes, your comments will appear below!!!