BREAKING NEWS

ÀWỌN OHUN ÀFIYÈSÍ TÍ A BÁ FẸ́ KÍ ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ÀMỌ̀TẸ́KÙN FẸSẸ̀ RINLẸ̀/ṢE ÀṢEYỌRÍ NÍ GÚÚSÙ ÌWỌ́ OÒRÙN NÀÌJÍRÍÀ

Láti Ààfin: Adégbénga Àkànnì Adéoyè(Oníṣọ̀kan Oòduà)


Bi a bá ń sọ̀rọ̀ nípa
"ÀMỌ̀TẸ́KÙN" ohun tó dára lásìkò yìí, tó yẹ kí ilẹ̀ Kóòótù-oò-jíire ní láti lè ṣe ààbò lórí ẹ̀mí àti dúkìá pàápàá ètò ààbò fún àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ, tí ojúlówó ọmọ Odùduwà àti ọmọ-ọkọ ilẹ̀ yìí ní láti gbajúmọ́ ni.


Àwọn ijọba wa ní láti bójútó àwọn nǹkan "MẸ́TA" wọ̀nyí kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà lè kẹ́sẹ-járí.
1. Ọ̀NÀ (Roads)
2. INÁ (Electricity)
3. OWÓ (Money)


Mo ṣe àkíyèsí pé púpọ̀ àwọn Ọ̀nà an wa ní Gúúsù ìwọ́ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló jẹ́ pé ó ti di kòtò ọ̀run tí èyí sì lè mú àkùdé bá iṣẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò "ÀMỌ̀TẸ́KÙN."


Gbogbo ìjọba ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn ní láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ láti rí i wí pé àwọn kojú iṣẹ́ Ọ̀nà ní ṣíṣe kí iṣẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò yìí lè já geere pàápàá ìjọba ìpínlẹ̀  "Ògùn, Ọ̀yọ́, Ọ̀ṣun, Èkìtì, apakan Kúwárà, Òndó titi tó fi dé ìpínlẹ̀ Ondó àti àwọn àgbègbè kan ní Kogí" ìpínlẹ̀  "Èkó" nìkan ló ṣì ṣẹ́pẹ́rẹ́ nípa ojú-ọ̀nà gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ti mo kọ́kọ́ mẹ́nu bà lókè yẹn ni wọ́n rẹ̀yìn púpọ̀ nípa àwọn Ọ̀nà tí ó wà ní àwọn ìgbèríko wọn nítorí púpọ̀ nínú àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ wọ̀nyí ló jẹ́ pé àwọn apákan olú ìlú ìpínlẹ̀ wọn ni wọ́n máa ń sáábà túnṣe tí àwọn ìlú káàkiri agbègbè máa jìyà àì ní Ọ̀nà tó já geere ti èyí sì lè ṣe idíwọ́ àti àkóbá fún àwọn ẹ̀ṣọ́ alabi.


ÀMỌ̀TẸ́KÙN láti kojú àwọn ẹni ibi "ajínigbé, aṣekúpani, ọ̀gárá ọlọ́ṣà àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ mìíràn láwùjọ.


INÁ
Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Olúwa sọ wí pé ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ìmọ́lẹ̀ sì wà ìmọ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ tó o bẹ́ẹ̀ gẹ̀ẹ́ òkùnkùn kankan kò lè borí i rẹ̀.


Àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ wọ̀nyí ni láti ṣiṣẹ́ lórí bí iná yóò ti ṣe máa tàn rokoṣo ni gbogbo àwọn agbègbè e wa èyí ni yóò mú kí iṣẹ́ náà rọrùn fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí àwọn ẹni ibi kò sí ní í rí ibi sápamọ́ sí láti ṣe iṣẹ́ ibi wọn nítorí àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní òru làá ṣèkà bẹ́nìkan ṣèkà lọ́sàn-án irú wọ́n kò ní fara ire lọ ṣùgbọ́n ti Iná bá wà ní Ààjìn òṣìkà gan-an ò ni fara re lọ nítorí ìmọ́lẹ̀ yóò wà láti rí aṣebàjẹ́.


Ìmọ́lẹ̀ yìí kan náà ni yóò ṣe aláàbò fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti mọ ibi tó yẹ kí kóówá wọn rìn sí nítorí kí ewu òru má ba à á wu wọn láti ọ̀dọ àwọn ẹni ibi nítorí "Màjà-mọ̀sá là á makínkanjú lógun akínkanjú tó bá mọ̀jà tí kò mọ̀sá irú u wọn máa ń bógun lọ ni."


Èyí tó tún yẹ kí àwọn ìjọba wa tún gbọ́dọ̀ bójútó náà ni bí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò wọ̀nyi yóò ti ṣe máa rí owó kí àwọn náà má tún máa bá gbàbọ̀dè fún wa ńtorí owó ló bojú ọ̀rẹ́ jẹ́ o._ _Owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo, owó ló ń mú kí ọ̀rẹ́ dùn, owó yìí kan náà ló ń ṣègboro._ _Ìjọba ní láti dá àjọ kan sílẹ̀ ti yóò máa bójútó ètò ìṣúná owó àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò.


"ÀMỌ̀TẸ́KÙN," aní láti máa ṣe kóríyâ fún wọn ni gbogbo ìgbà yàtọ̀ sí owó ọ̀yà a wọn nítorí kú iṣẹ́ ló ń mórí òṣìṣẹ́ ẹ yá, ó pọn dandan kí ìjọba má ṣe fi owó jẹ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò yìí níyà nítorí àwọn náà ní ẹbí tí wọ́n ni láti tọjú.


Bákan náà, owó yìí kan náà ni wọ́n nílò láti fi pèsè ààbò fún ara wọn nípa àwọn agbára àwọn bàba-ńlá a wa àti àwọn àjẹsára lÓríṣiríṣi ti yóò dúró fún ààbò àwọn tìkalára.


Lákòótán, ìjọba ni láti ní àwọn ikọ̀ mìíràn tí yóò máa bójútó àwọn iṣẹ́ ti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ÀMỌ̀TẸ́KÙN yóò máa ṣe nítorí ó ṣeé ṣe kí á ri alágbára má mèrò, agbẹ̀yìn-bẹbọ-jẹ́ ti yóò máa ṣi agbára lò ti ìjìyà tó gbópọn sì gbọdọ̀ wà fún irúfẹ́ ẹni tí àjé ìwà òbàyéjẹ́ bá já lé lórí yàtọ̀ sí ìbúra, ìmùlẹ̀ tó ti ṣe kí ó tóo gbaṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò.



Tí gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kò bá sí lójú iṣẹ́ àti ìṣe yóò ṣòro fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbo ÀMỌ̀TẸ́KÙN àti ìjọba láti borí àwọn agbéṣùnmọ̀mí kàkà bẹ́ẹ̀ a ó kàn máa fi ẹ̀mí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò wewu ni tí a sì gbọdọ̀ máa rántí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí náà ni ẹbí tí wọn yóò jábọ̀ iṣẹ́ ìríjú wọn fún nílé.

Adégbénga Àkànnì Adéoyè(Oníṣọ̀kan Oòduà)
Olùdásílẹ̀ "ÌṢỌ̀KAN ỌMỌ ODÙDUWÀ FOUNDATION" (ISOOF).
Fi Ìtàn rẹ ránṣẹ́, ìpolówó ọjà, ayẹyẹ, àjọ̀dún oríkádún, ìkíni, ìpolongo, àwòṣe, ẹ̀yà, àwọn ohun tó o bá fẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀, atbbl... pẹ̀lú u wa. Ẹ pè wá tàbí kí ẹ báwa fi àtẹ̀ránṣẹ́ jẹwọ̀ lórí òǹkà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yìí pẹ̀lú olóòtú u wa (WhatsApp) +2348072633727, Email: voiceairmedia@gmail.com

KÀ SÍWÁJÚ SÍ I LÓRÍ I FÓÒNÙ RẸ FÚN ÌMỌ̀ KÍKÚN LÓRÍ ÀWỌN ÌRÒYÌN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ LÁWÙJỌ ÀTI ÀGBÁYÉ


No comments

After Dropping your comment, Wait for few minutes, your comments will appear below!!!